-
1 Àwọn Ọba 21:8-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Torí náà, ó kọ àwọn lẹ́tà ní orúkọ Áhábù, ó gbé èdìdì ọba+ lé e, ó sì fi àwọn lẹ́tà náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbààgbà+ àti àwọn èèyàn pàtàkì tó ń gbé ní ìlú Nábótì. 9 Ó kọ ọ́ sínú àwọn lẹ́tà náà pé: “Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì ní kí Nábótì jókòó sí iwájú gbogbo àwọn èèyàn náà. 10 Kí ẹ ní kí ọkùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ aláìníláárí jókòó síwájú rẹ̀, kí wọ́n sì ta kò ó+ pé, ‘O ti sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run àti sí ọba!’+ Lẹ́yìn náà, kí ẹ mú un jáde, kí ẹ sì sọ ọ́ lókùúta pa.”+
11 Torí náà, àwọn ọkùnrin ìlú rẹ̀, àwọn àgbààgbà àti àwọn èèyàn pàtàkì tó ń gbé ìlú rẹ̀ ṣe ohun tó wà nínú lẹ́tà tí Jésíbẹ́lì fi ránṣẹ́ sí wọn.
-
-
Jeremáyà 38:4, 5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Àwọn ìjòyè sọ fún ọba pé: “Jọ̀wọ́, ní kí wọ́n pa ọkùnrin yìí,+ torí bó ṣe máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn* àwọn ọmọ ogun tó ṣẹ́ kù nínú ìlú yìí àti gbogbo àwọn èèyàn náà nìyẹn, tó ń sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fún wọn. Nítorí kì í ṣe àlàáfíà àwọn èèyàn yìí ni ọkùnrin yìí ń wá, bí kò ṣe àjálù wọn.” 5 Ọba Sedekáyà dáhùn pé: “Ẹ wò ó! Ọwọ́ yín ni ọkùnrin náà wà, torí kò sí nǹkan kan tí ọba lè ṣe láti dá yín dúró.”
-