-
Nọ́ńbà 23:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Àwọn èèyàn yìí yóò dìde bíi kìnnìún,
Bíi kìnnìún ni yóò gbé ara rẹ̀ sókè.+
Kò ní dùbúlẹ̀ títí yóò fi jẹ ẹran tó bá mú
Tó sì máa mu ẹ̀jẹ̀ àwọn tó bá pa.”
-
-
Àìsáyà 31:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Torí ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí:
“Bí kìnnìún, ìyẹn ọmọ kìnnìún tó lágbára,* ṣe ń kùn lórí ẹran tó pa,
Nígbà tí a pe odindi àwùjọ àwọn olùṣọ́ àgùntàn sí i,
Tí ohùn wọn ò dẹ́rù bà á,
Tí gìrìgìrì wọn ò sì kó jìnnìjìnnì bá a,
Bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa sọ̀ kalẹ̀ wá ja ogun
Lórí Òkè Síónì àti lórí òkè kékeré rẹ̀.
-