ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 62:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Bákan náà, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ jẹ́ tìrẹ, Jèhófà,+

      Nítorí o máa ń san kálukú lẹ́san iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+

  • Oníwàásù 11:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Máa yọ̀, ìwọ ọ̀dọ́kùnrin, nígbà tí o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, sì jẹ́ kí ọkàn rẹ máa yọ̀ ní ìgbà ọ̀dọ́ rẹ. Máa ṣe ohun tí ọkàn rẹ bá sọ, sì máa lọ síbi tí ojú rẹ bá darí rẹ sí; ṣùgbọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run tòótọ́ máa dá ọ lẹ́jọ́* lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí.+

  • Mátíù 12:36, 37
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 36 Mò ń sọ fún yín pé ní Ọjọ́ Ìdájọ́, àwọn èèyàn máa jíhìn+ gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò wúlò tí wọ́n sọ; 37 torí ọ̀rọ̀ yín la máa fi pè yín ní olódodo, ọ̀rọ̀ yín la sì máa fi dá yín lẹ́bi.”

  • Ìṣe 17:31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 Torí ó ti dá ọjọ́ kan tó máa fi òdodo ṣèdájọ́ + ayé láti ọwọ́ ọkùnrin kan tó ti yàn, ó sì ti pèsè ẹ̀rí tó dájú fún gbogbo èèyàn bó ṣe jí i dìde kúrò nínú ikú.”+

  • 2 Kọ́ríńtì 5:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Nítorí gbogbo wa ló máa fara hàn* níwájú ìjókòó ìdájọ́ Kristi, kí kálukú lè gba èrè àwọn ohun tó ṣe nígbà tó wà nínú ara, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú.*+

  • 1 Tímótì 5:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Àwọn kan wà tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn máa ń hàn sí ọ̀pọ̀ èèyàn, ó sì máa ń yọrí sí ìdájọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn míì máa ń hàn síta nígbà tó bá yá.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́