40 Oòrùn máa ń pa mí lọ́sàn-án, òtútù máa ń mú mi lóru, oorun sì máa ń dá lójú mi.+ 41 Ó ti pé ogún (20) ọdún báyìí tí mo ti wà nílé rẹ. Mo fi ọdún mẹ́rìnlá (14) sìn ọ́ torí àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì, mo sì fi ọdún mẹ́fà sìn ọ́ torí agbo ẹran rẹ, ìgbà mẹ́wàá+ lo yí ohun tó yẹ kó jẹ́ èrè mi pa dà.