- 
	                        
            
            Orin Sólómọ́nì 4:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        4 “Wò ó! O rẹwà gan-an, olólùfẹ́ mi. Wò ó! O rẹwà gan-an. Ojú rẹ rí bíi ti àdàbà, lábẹ́ aṣọ tí o fi bojú. Irun rẹ dà bí agbo ewúrẹ́ Tí wọ́n ń rọ́ bọ̀ láti orí àwọn òkè Gílíádì.+ 2 Eyín rẹ dà bí agbo àgùntàn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gé irun wọn, Tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wẹ̀ fún, Gbogbo wọn bí ìbejì, Ọmọ ìkankan nínú wọn ò sì sọ nù. 3 Ètè rẹ rí bí òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sì dùn. Ẹ̀rẹ̀kẹ́* rẹ rí bí awẹ́ pómégíránétì Lábẹ́ aṣọ tí o fi bojú. 
 
-