13 Dìde, kí o sì pakà, ìwọ ọmọbìnrin Síónì;+
Torí èmi yóò sọ ìwo rẹ di irin,
Màá sọ àwọn pátákò rẹ di bàbà,
Ìwọ yóò sì pa ọ̀pọ̀ èèyàn run.+
Ìwọ yóò fún Jèhófà ní ohun tí wọ́n fi èrú kó jọ,
Ìwọ yóò sì fún Olúwa gbogbo ilẹ̀ ayé ní àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn.”+