-
Mátíù 12:15-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Nígbà tí Jésù mọ èyí, ó kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn tún tẹ̀ lé e,+ ó sì wo gbogbo wọn sàn, 16 àmọ́ ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òun,+ 17 kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ, ẹni tó sọ pé:
18 “Wò ó! Ìránṣẹ́ mi+ tí mo yàn, àyànfẹ́ mi, ẹni tí mo* tẹ́wọ́ gbà!+ Màá fi ẹ̀mí mi sára rẹ̀,+ ó sì máa jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo ṣe kedere sí àwọn orílẹ̀-èdè.
-