28 Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tó ń ṣe làálàá, tí a di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, màá sì tù yín lára. 29 Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, torí oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni mí,+ ara sì máa tù yín.*
17 Bákan náà, ó ní láti dà bí “àwọn arákùnrin” rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà,+ kó lè di àlùfáà àgbà tó jẹ́ aláàánú àti olóòótọ́ nínú àwọn ohun tó jẹ mọ́ ti Ọlọ́run, kó lè rú ẹbọ ìpẹ̀tù*+ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn.+