Àìsáyà 30:23 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 23 Ó máa rọ òjò sí ohun tí o gbìn sínú ilẹ̀,+ oúnjẹ tí ilẹ̀ bá sì mú jáde máa pọ̀ rẹpẹtẹ, ó sì máa lọ́ràá.*+ Ní ọjọ́ yẹn, ẹran ọ̀sìn rẹ máa jẹko ní àwọn pápá tó fẹ̀.+ Jóẹ́lì 3:18 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 18 Wáìnì dídùn yóò máa sẹ̀ láti orí àwọn òkè ní ọjọ́ yẹn,+Wàrà yóò máa ṣàn lórí àwọn òkè kéékèèké,Gbogbo omi odò Júdà yóò sì máa ṣàn. Omi yóò sun láti ilé Jèhófà,+Yóò sì bomi rin Àfonífojì Àwọn Igi Bọn-ọ̀n-ní. Sekaráyà 9:17 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 17 Oore rẹ̀ mà pọ̀ o,+Ó mà lẹ́wà gan-an o! Ọkà yóò mú kí àwọn géńdé ọkùnrin lágbára,Wáìnì tuntun yóò sì fún àwọn wúńdíá lókun.”+
23 Ó máa rọ òjò sí ohun tí o gbìn sínú ilẹ̀,+ oúnjẹ tí ilẹ̀ bá sì mú jáde máa pọ̀ rẹpẹtẹ, ó sì máa lọ́ràá.*+ Ní ọjọ́ yẹn, ẹran ọ̀sìn rẹ máa jẹko ní àwọn pápá tó fẹ̀.+
18 Wáìnì dídùn yóò máa sẹ̀ láti orí àwọn òkè ní ọjọ́ yẹn,+Wàrà yóò máa ṣàn lórí àwọn òkè kéékèèké,Gbogbo omi odò Júdà yóò sì máa ṣàn. Omi yóò sun láti ilé Jèhófà,+Yóò sì bomi rin Àfonífojì Àwọn Igi Bọn-ọ̀n-ní.
17 Oore rẹ̀ mà pọ̀ o,+Ó mà lẹ́wà gan-an o! Ọkà yóò mú kí àwọn géńdé ọkùnrin lágbára,Wáìnì tuntun yóò sì fún àwọn wúńdíá lókun.”+