-
Ìsíkíẹ́lì 22:20-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Bí ìgbà tí wọ́n bá kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti tánganran jọ sínú iná ìléru, kí wọ́n lè koná mọ́ ọn kí wọ́n sì yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni màá fi ìbínú àti ìrunú kó yín jọ, màá koná mọ́ yín, màá sì yọ́ yín.+ 21 Èmi yóò kó yín jọ, èmi yóò koná ìbínú mi mọ́ yín,+ ẹ ó sì yọ́ nínú rẹ̀.+ 22 Bí fàdákà ṣe ń yọ́ nínú iná ìléru, bẹ́ẹ̀ ni ẹ ó ṣe yọ́ nínú rẹ̀; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ti bínú sí yín gan-an.’”
-