21 “Ẹ ro ẹjọ́ yín,” ni Jèhófà wí.
“Ẹ gbèjà ara yín,” ni Ọba Jékọ́bù wí.
22 “Ẹ mú ẹ̀rí wá, kí ẹ sì sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ fún wa.
Ẹ sọ àwọn ohun àtijọ́ fún wa,
Ká lè ronú nípa wọn, ká sì mọ ibi tí wọ́n máa já sí.
Tàbí kí ẹ kéde àwọn ohun tó ń bọ̀ fún wa.+