-
Àìsáyà 44:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Ó fi iná sun ìdajì rẹ̀;
Ìdajì yẹn ló fi yan ẹran tó ń jẹ, ó sì yó.
Ó tún yáná, ó wá sọ pé:
“Áà! Ara mi ti móoru bí mo ṣe ń wo iná yìí.”
17 Àmọ́ ó fi èyí tó ṣẹ́ kù ṣe ọlọ́run, ó fi ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ̀.
Ó ń forí balẹ̀ fún un, ó sì ń sìn ín,
Ó ń gbàdúrà sí i, ó sì ń sọ pé:
“Gbà mí, torí ìwọ ni ọlọ́run mi.”+
-
-
Dáníẹ́lì 3:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn púpọ̀, háàpù onígun mẹ́ta, ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín, fèrè alápò awọ àti gbogbo ohun ìkọrin míì, kí ẹ wólẹ̀, kí ẹ sì jọ́sìn ère wúrà tí Ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀.
-