21 Ní ọ̀sán, Jèhófà máa ń lọ níwájú wọn nínú ọwọ̀n ìkùukùu* kó lè máa darí wọn lójú ọ̀nà,+ àmọ́ ní òru, ó máa ń lọ níwájú wọn nínú ọwọ̀n iná* kó lè fún wọn ní ìmọ́lẹ̀, kí wọ́n lè máa bá ìrìn àjò wọn lọ tọ̀sántòru.+
15 Tí o bá ti gbọ́ ìró tó ń dún bí ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi bákà, kí o dojú ìjà kọ wọ́n, nítorí Ọlọ́run tòótọ́ yóò ti lọ ṣáájú rẹ láti ṣá àwọn ọmọ ogun Filísínì balẹ̀.”+