ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sekaráyà 11:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Sọ owó náà sí ibi ìṣúra, iye tó jọjú tí wọ́n rò pé ó tọ́ sí mi.”+ Torí náà, mo mú ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà náà, mo sì sọ ọ́ sí ibi ìṣúra ní ilé Jèhófà.+

  • Jòhánù 18:39, 40
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 39 Àmọ́, ẹ ní àṣà kan, pé kí n máa tú ẹnì kan sílẹ̀ fún yín nígbà Ìrékọjá.+ Torí náà, ṣé ẹ fẹ́ kí n tú Ọba Àwọn Júù sílẹ̀ fún yín?” 40 Wọ́n bá tún kígbe pé: “A ò fẹ́ ọkùnrin yìí, Bárábà la fẹ́!” Àmọ́ olè ni Bárábà.+

  • Ìṣe 3:13, 14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Ọlọ́run Ábúráhámù àti ti Ísákì àti ti Jékọ́bù,+ Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, ti ṣe Jésù,+ Ìránṣẹ́ rẹ̀ lógo,+ ẹni tí ẹ fà lé àwọn èèyàn lọ́wọ́,+ tí ẹ sì sọ níwájú Pílátù pé ẹ ò mọ̀ rí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pinnu pé òun máa dá a sílẹ̀. 14 Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ sọ pé ẹ ò mọ ẹni mímọ́ àti olódodo yẹn rí, ẹ sì ní kí wọ́n fún yín ní ọkùnrin tó jẹ́ apààyàn,+

  • Ìṣe 4:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Jésù yìí ni ‘òkúta tí ẹ̀yin kọ́lékọ́lé ò kà sí tó ti wá di olórí òkúta igun ilé.’*+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́