10 “Màá tú ẹ̀mí ojú rere àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ sórí ilé Dáfídì àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù, wọ́n máa wo ẹni tí wọ́n gún,+ wọ́n sì máa pohùn réré ẹkún torí rẹ̀ bí ìgbà tí wọ́n ń sunkún torí ọmọkùnrin kan ṣoṣo; wọ́n sì máa ṣọ̀fọ̀ gan-an torí rẹ̀ bí ìgbà tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ torí àkọ́bí ọmọkùnrin.