-
Jeremáyà 34:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Lẹ́nu àìpẹ́* yìí, ẹ̀yin fúnra yín yí pa dà, ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi torí pé ẹ kéde òmìnira fún ọmọnìkejì yín, ẹ sì dá májẹ̀mú níwájú mi nínú ilé tí a fi orúkọ mi pè. 16 Àmọ́ lẹ́yìn náà, ẹ yí pa dà, ẹ sì kó ẹ̀gàn bá orúkọ mi,+ nítorí kálukú yín mú ẹrú rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin pa dà wá, àwọn tí ẹ ti jẹ́ kí wọ́n lọ ní òmìnira bó ṣe wù wọ́n,* ẹ sì tún sọ wọ́n di ẹrú pa dà tipátipá.’
-
-
Míkà 3:2-4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Àmọ́ ẹ kórìíra ohun rere,+ ẹ sì fẹ́ràn ohun búburú;+
Ẹ bó àwọn èèyàn mi láwọ, ẹ sì ṣí ẹran kúrò lára egungun wọn.+
3 Ẹ tún jẹ ẹran ara àwọn èèyàn mi,+
Ẹ sì bó wọn láwọ,
Ẹ fọ́ egungun wọn, ẹ sì rún un sí wẹ́wẹ́,+
Bí ohun tí wọ́n sè nínú ìkòkò,* bí ẹran nínú ìkòkò oúnjẹ.
4 Ní àkókò yẹn, wọ́n á ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́,
Àmọ́ kò ní dá wọn lóhùn.
-