21 O sì máa sọ lọ́kàn rẹ pé,
‘Ta ni bàbá àwọn ọmọ mi yìí,
Ṣebí obìnrin tó ti ṣòfò ọmọ ni mí, tí mo sì yàgàn,
Tí mo lọ sí ìgbèkùn, tí wọ́n sì mú mi ní ẹlẹ́wọ̀n?
Ta ló tọ́ àwọn ọmọ yìí?+
Wò ó! Wọ́n fi èmi nìkan sílẹ̀,+
Ibo wá ni àwọn yìí ti wá?’”+
22 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Wò ó! Màá gbé ọwọ́ mi sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè,
Màá sì gbé àmì mi sókè sí àwọn èèyàn.+
Wọ́n máa fi ọwọ́ wọn gbé àwọn ọmọkùnrin rẹ wá,
Wọ́n sì máa gbé àwọn ọmọbìnrin rẹ sí èjìká wọn.+