6 “Torí pé àwọn èèyàn yìí ti pa omi Ṣílóà tó rọra ń ṣàn tì,+
Tí wọ́n sì ń yọ̀ torí Résínì àti ọmọ Remaláyà,+
7 Torí náà, wò ó! Jèhófà máa mú kí
Ibú omi Odò ńlá náà ya lù wọ́n,
Ọba Ásíríà+ àti gbogbo ògo rẹ̀.
Ó máa wá sórí gbogbo ibi tí omi rẹ̀ ń ṣàn gbà,
Ó máa kún bo gbogbo bèbè rẹ̀,