-
Lúùkù 4:17-21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Torí náà, wọ́n fún un ní àkájọ ìwé wòlíì Àìsáyà, ó ṣí àkájọ ìwé náà, ó sì rí ibi tí wọ́n kọ ọ́ sí pé: 18 “Ẹ̀mí Jèhófà* wà lára mi, torí ó ti yàn mí kí n lè kéde ìhìn rere fún àwọn aláìní. Ó rán mi láti kéde òmìnira fún àwọn ẹrú, pé àwọn afọ́jú máa pa dà ríran, láti mú kí àwọn tí wọ́n tẹ̀ rẹ́ máa lọ lómìnira,+ 19 láti wàásù ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.”*+ 20 Ló bá ká àkájọ ìwé náà, ó dá a pa dà fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó; gbogbo àwọn tó wà nínú sínágọ́gù sì tẹjú mọ́ ọn. 21 Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún wọn pé: “Òní ni ìwé mímọ́ tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ yìí ṣẹ.”+
-
-
Ìṣe 26:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Màá sì gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn yìí àti lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí màá rán ọ sí+ 18 láti la ojú wọn,+ láti mú wọn kúrò nínú òkùnkùn+ wá sínú ìmọ́lẹ̀+ àti láti mú wọn kúrò lábẹ́ àṣẹ Sátánì+ wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà,+ kí wọ́n sì rí ogún láàárín àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn nínú mi ti sọ wọ́n di mímọ́.’
-