33 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Ní ọjọ́ tí mo bá wẹ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀bi yín, èmi yóò mú kí wọ́n máa gbé inú àwọn ìlú náà,+ màá sì mú kí wọ́n tún àwọn àwókù kọ́.+ 34 Wọ́n á dáko sí ilẹ̀ tó ti di ahoro tí gbogbo àwọn tó ń kọjá lọ ń wò.