6 Ní ọdún kẹsàn-án Hóṣéà, ọba Ásíríà gba Samáríà.+ Ó wá kó àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ní ìgbèkùn+ lọ sí Ásíríà, ó sì mú kí wọ́n máa gbé ní Hálà àti ní Hábórì níbi odò Gósánì+ àti ní àwọn ìlú àwọn ará Mídíà.+
6 Ó tún lóyún, ó sì bí ọmọbìnrin kan. Ọlọ́run wá sọ fún Hósíà pé: “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-ruhámà,* torí mi ò ní ṣàánú+ ilé Ísírẹ́lì mọ́, ṣe ni màá lé wọn dà nù.+