ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 130:6-8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Mò* ń retí Jèhófà,+

      Ju bí àwọn olùṣọ́ ṣe ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́,+

      Àní, ju bí àwọn olùṣọ́ ṣe ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́.

      7 Kí Ísírẹ́lì máa dúró de Jèhófà,

      Nítorí ìfẹ́ Jèhófà kì í yẹ̀,+

      Ó sì ní agbára ńlá tó lè fi rani pa dà.

      8 Yóò ra Ísírẹ́lì pa dà nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  • Àìsáyà 25:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  9 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa sọ pé:

      “Wò ó! Ọlọ́run wa nìyí!+

      A ti gbẹ́kẹ̀ lé e,+

      Ó sì máa gbà wá là.+

      Jèhófà nìyí!

      A ti gbẹ́kẹ̀ lé e.

      Ẹ jẹ́ ká máa yọ̀, kí inú wa sì dùn torí ìgbàlà rẹ̀.”+

  • Míkà 7:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Àmọ́ ní tèmi, èmi yóò máa retí Jèhófà.+

      Màá dúró* de Ọlọ́run ìgbàlà mi.+

      Ọlọ́run mi yóò gbọ́ mi.+

  • 1 Kọ́ríńtì 2:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Àmọ́, bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ojú kò tíì rí, etí kò sì tíì gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn èèyàn kò tíì ro àwọn ohun tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́