12 “‘“Táṣíṣì+ bá ọ dòwò pọ̀ torí ọrọ̀ rẹ pọ̀ rẹpẹtẹ.+ Fàdákà, irin, tánganran àti òjé ni wọ́n fi ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ.+ 13 Jáfánì, Túbálì+ àti Méṣékì+ bá ọ dòwò pọ̀, wọ́n sì fi àwọn ohun tí wọ́n fi bàbà ṣe àti àwọn ẹrú+ ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́dọ̀ rẹ.