ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 21:42
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 42 Jésù sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ ò tíì kà á nínú Ìwé Mímọ́ rí pé, ‘Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀, òun ló wá di olórí òkúta igun ilé.*+ Ọ̀dọ̀ Jèhófà* ni èyí ti wá, ó sì jẹ́ ìyanu lójú wa’?+

  • Mátíù 21:44
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 44 Bákan náà, ẹni tó bá kọ lu òkúta yìí máa fọ́ túútúú.+ Tó bá sì bọ́ lu ẹnikẹ́ni, ó máa rún ẹni náà wómúwómú.”+

  • Lúùkù 20:17, 18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Àmọ́ ó wò wọ́n tààràtà, ó sì sọ pé: “Kí wá ni èyí túmọ̀ sí, ohun tí a kọ pé, ‘Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀, òun ló wá di olórí òkúta igun ilé’?*+ 18 Gbogbo ẹni tó bá kọ lu òkúta yẹn máa fọ́ túútúú.+ Tó bá sì bọ́ lu ẹnikẹ́ni, ó máa rún ẹni náà wómúwómú.”

  • Róòmù 9:31-33
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 àmọ́ bí Ísírẹ́lì tiẹ̀ ń lépa òfin òdodo, ọwọ́ rẹ̀ kò tẹ òfin náà. 32 Kí nìdí? Torí pé wọ́n lépa rẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́, kì í ṣe nípa ìgbàgbọ́. Wọ́n kọsẹ̀ lára “òkúta ìkọ̀sẹ̀”+ náà; 33 bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Wò ó! Màá fi òkúta+ ìkọ̀sẹ̀ kan àti àpáta agbéniṣubú lélẹ̀ ní Síónì, àmọ́ ẹni tó bá gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lé e kò ní rí ìjákulẹ̀.”+

  • 1 Kọ́ríńtì 1:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 àmọ́ àwa ń wàásù Kristi tí wọ́n kàn mọ́gi,* lójú àwọn Júù, ó jẹ́ ohun tó ń fa ìkọ̀sẹ̀ àmọ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè, ó jẹ́ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀.+

  • 1 Pétérù 2:7, 8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Nítorí náà, ẹ̀yin ló ṣe iyebíye fún, torí ẹ jẹ́ onígbàgbọ́; àmọ́ fún àwọn tí kò gbà gbọ́, “òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀,+ òun ló wá di olórí òkúta igun ilé”*+ 8 àti “òkúta ìkọ̀sẹ̀ kan àti àpáta agbéniṣubú.”+ Wọ́n ń kọsẹ̀ torí wọn ò ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà. Ìdí tí a fi yàn wọ́n nìyí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́