35 ‘Màá gbèjà ìlú yìí,+ màá sì gbà á sílẹ̀ nítorí orúkọ mi+
Àti nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi.’”+
36 Áńgẹ́lì Jèhófà wá jáde lọ, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún márùn-ún (185,000) ọkùnrin nínú ibùdó àwọn ará Ásíríà. Nígbà tí àwọn èèyàn jí láàárọ̀ kùtù, wọ́n rí òkú nílẹ̀ bẹẹrẹbẹ.+