11 Mo rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, wò ó! ẹṣin funfun kan.+ A pe ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ ní Ẹni Tó Ṣeé Gbára Lé+ àti Olóòótọ́,+ ó ń ṣèdájọ́, ó sì ń fi òdodo+ jagun lọ.
15 Idà tó mú, tó sì gùn jáde láti ẹnu rẹ̀,+ kó lè fi pa àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn.+ Bákan náà, ó ń tẹ ìbínú àti ìrunú Ọlọ́run Olódùmarè níbi tí a ti ń fún wáìnì.+