24 Jèhófà wá rọ òjò imí ọjọ́ àti iná lé Sódómù àti Gòmórà lórí, ó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà, láti ọ̀run.+25 Ó run àwọn ìlú yìí, àní, gbogbo agbègbè náà, títí kan àwọn tó ń gbé àwọn ìlú náà àti àwọn ewéko ilẹ̀.+
40 “Bí Ọlọ́run ṣe pa Sódómù àti Gòmórà+ àti àwọn ìlú tó yí wọn ká run,”+ ni Jèhófà wí, “kò ní sí ẹnì kankan tí á máa gbé ibẹ̀, kò sì ní sí èèyàn kankan tó máa tẹ̀ dó síbẹ̀.+