15 Mósè pín ogún fún ẹ̀yà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ní ìdílé-ìdílé, 16 ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Áróérì, tó wà létí Àfonífojì Áánónì àti ìlú tó wà láàárín àfonífojì náà pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ tó tẹ́jú lẹ́gbẹ̀ẹ́ Médébà; 17 Hẹ́ṣíbónì àti gbogbo ìlú rẹ̀+ tó wà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú, Díbónì, Bamoti-báálì, Bẹti-baali-méónì,+