-
2 Àwọn Ọba 17:25, 26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibẹ̀, wọn kò bẹ̀rù* Jèhófà. Nítorí náà, Jèhófà rán àwọn kìnnìún sáàárín wọn,+ wọ́n sì pa lára àwọn èèyàn náà. 26 Wọ́n ròyìn fún ọba Ásíríà pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè tí o kó lọ sí ìgbèkùn, tí o ní kí wọ́n máa gbé àwọn ìlú Samáríà kò mọ ẹ̀sìn* Ọlọ́run ilẹ̀ náà. Torí náà, ó ń rán àwọn kìnnìún sáàárín wọn, àwọn kìnnìún náà sì ń pa wọ́n, torí pé kò sí ìkankan nínú wọn tó mọ ẹ̀sìn Ọlọ́run ilẹ̀ náà.”
-