-
Jóṣúà 13:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Mósè pín ogún fún ẹ̀yà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ní ìdílé-ìdílé, 16 ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ láti Áróérì, tó wà létí Àfonífojì Áánónì àti ìlú tó wà láàárín àfonífojì náà pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ tó tẹ́jú lẹ́gbẹ̀ẹ́ Médébà;
-
-
2 Àwọn Ọba 10:32, 33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Lákòókò yẹn, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í gé* ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì kù. Hásáẹ́lì ń kọ lù wọ́n léraléra káàkiri ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì,+ 33 láti Jọ́dánì sápá ìlà oòrùn, gbogbo ilẹ̀ Gílíádì, níbi tí ẹ̀yà Gádì, ẹ̀yà Rúbẹ́nì àti ẹ̀yà Mánásè+ ń gbé. Ìpínlẹ̀ Áróérì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Àfonífojì Áánónì títí dé Gílíádì àti Báṣánì wà lára wọn.+
-