8 Torí èyí, màá pohùn réré ẹkún, màá sì hu;+
Èmi yóò rìn láìwọ bàtà àti ní ìhòòhò.+
Màá pohùn réré ẹkún bí ajáko,
Èmi yóò sì ṣọ̀fọ̀ bí ògòǹgò.
9 Torí ọgbẹ́ rẹ̀ kò lè jinná;+
Ó ti dé Júdà lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún.+
Egbò náà ti ràn dé ẹnubodè àwọn èèyàn mi, dé Jerúsálẹ́mù.+