41 Fáráò tún sọ fún Jósẹ́fù pé: “Wò ó, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.”+42 Fáráò wá bọ́ òrùka àṣẹ tó wà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi sí ọwọ́ Jósẹ́fù. Ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa fún un, ó sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn.
15 Módékáì wá jáde níwájú ọba nínú ẹ̀wù oyè olówùú búlúù àti funfun,* ó dé adé ńlá tí wọ́n fi wúrà ṣe, ó sì wọ aṣọ àwọ̀lékè àtàtà olówùú pọ́pù.+ Igbe ayọ̀ sì sọ ní ìlú Ṣúṣánì.*