2 “Ọmọ èèyàn, sọ fún aṣáájú Tírè pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Torí pé ò ń gbéra ga nínú ọkàn rẹ,+ tí o sì ń sọ pé, ‘ọlọ́run ni mí.
Orí ìtẹ́ ọlọ́run ni mo jókòó sí láàárín òkun.’+
Àmọ́ èèyàn lásán ni ọ́, o kì í ṣe ọlọ́run,
Bí o tiẹ̀ ń pe ara rẹ ní ọlọ́run nínú ọkàn rẹ.