-
Míkà 3:9-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ẹ jọ̀ọ́, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin olórí ilé Jékọ́bù
Àti ẹ̀yin aláṣẹ ilé Ísírẹ́lì,+
Tí ẹ kórìíra ìdájọ́ òdodo, tí ẹ sì ń yí gbogbo ọ̀rọ̀ po,+
10 Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ìtàjẹ̀sílẹ̀ kọ́ Síónì, tí ẹ sì ń fi àìṣòdodo kọ́ Jerúsálẹ́mù.+
Síbẹ̀ wọ́n gbára lé Jèhófà,* wọ́n ń sọ pé:
“Ṣebí Jèhófà wà pẹ̀lú wa?+
Àjálù kankan ò lè dé bá wa.”+
-