19 Nítorí náà, ẹ kì í ṣe àjèjì tàbí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè mọ́,+ àmọ́ ẹ jẹ́ aráàlú+ pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì jẹ́ ara agbo ilé Ọlọ́run,+ 20 a sì ti kọ́ yín sórí ìpìlẹ̀ àwọn àpọ́sítélì àti àwọn wòlíì,+ nígbà tí Kristi Jésù fúnra rẹ̀ jẹ́ òkúta ìpìlẹ̀ igun ilé.+