-
Diutarónómì 28:53-55Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
53 O sì máa wá jẹ àwọn ọmọ* rẹ, ẹran ara àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin+ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ, torí bí nǹkan ṣe máa le tó nígbà tí wọ́n bá dó tì ọ́ àti torí wàhálà tí àwọn ọ̀tá rẹ máa kó bá ọ.
54 “Ọkùnrin tí kò lágbaja rárá, tó sì lójú àánú láàárín rẹ kò tiẹ̀ ní ṣàánú arákùnrin rẹ̀ tàbí ìyàwó rẹ̀ tó fẹ́ràn tàbí àwọn ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ́ kù, 55 kò sì ní fún wọn ní ìkankan lára ẹran ara àwọn ọmọ rẹ̀ tó máa jẹ, torí kò ní nǹkan kan mọ́ nítorí bí àwọn ọ̀tá ṣe dó tì ọ́ àti bí wàhálà tí wọ́n kó bá àwọn ìlú+ rẹ ṣe pọ̀ tó.
-