-
Sáàmù 72:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
72 Ọlọ́run, sọ àwọn ìdájọ́ rẹ fún ọba,
Kí o sì kọ́ ọmọ ọba ní òdodo rẹ.+
-
-
Míkà 4:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Máa fìdí múlẹ̀ gbọn-in sórí àwọn òkè,
A sì máa gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ,
Àwọn èèyàn á sì máa rọ́ lọ síbẹ̀.+
2 Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè máa lọ, wọ́n á sì sọ pé:
“Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká lọ sórí òkè Jèhófà,
Sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù.+
Ó máa kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà rẹ̀,
A ó sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.”
Torí òfin* máa jáde láti Síónì,
Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì máa jáde láti Jerúsálẹ́mù.
3 Ó máa ṣe ìdájọ́ láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn,+
Ó sì máa yanjú* ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè alágbára tí ọ̀nà wọn jìn.
Wọ́n máa fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀,
Wọ́n sì máa fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn.+
Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,
Wọn ò sì ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.+
-