3 Ó máa ṣe ìdájọ́ láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn,+
Ó sì máa yanjú ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè alágbára tí ọ̀nà wọn jìn.
Wọ́n máa fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀,
Wọ́n sì máa fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn.+
Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,
Wọn ò sì ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.+
4 Kálukú wọn máa jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀,+
Ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n,+
Torí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló fi ẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́.