16 Ní ọjọ́ yẹn, a ó sọ fún Jerúsálẹ́mù pé:
“Má bẹ̀rù, ìwọ Síónì.+
Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ domi.
17 Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà ní àárín rẹ.+
Ó máa gbani là bí Alágbára ńlá.
Ó máa yọ̀ gidigidi nítorí rẹ.+
Á dákẹ́ jẹ́ẹ́ nínú ìfẹ́ rẹ̀.
Á dunnú nítorí rẹ pẹ̀lú igbe ayọ̀.