-
Máàkù 7:32-35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Wọ́n mú ọkùnrin adití kan tí kò lè sọ̀rọ̀ dáadáa wá bá a níbẹ̀,+ wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé kó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e. 33 Ó mú ọkùnrin yẹn nìkan kúrò lọ́dọ̀ àwọn èrò náà lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Ó ki ìka rẹ̀ bọ etí ọkùnrin náà méjèèjì, lẹ́yìn tó tutọ́, ó fọwọ́ kan ahọ́n rẹ̀.+ 34 Ó gbójú sókè ọ̀run, ó mí kanlẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Éfátà,” tó túmọ̀ sí, “Là.” 35 Ni etí ọkùnrin náà bá là,+ kò níṣòro ọ̀rọ̀ sísọ mọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ dáadáa.
-