-
Ìṣe 8:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Nítorí ọ̀pọ̀ ló ní àwọn ẹ̀mí àìmọ́, àwọn ẹ̀mí yìí á kígbe ní ohùn rara, wọ́n á sì jáde.+ Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn tó ní àrùn rọpárọsẹ̀ àti àwọn tó yarọ rí ìwòsàn.
-
-
Ìṣe 14:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ní Lísírà, ọkùnrin kan wà ní ìjókòó tí ẹsẹ̀ rẹ̀ rọ. Àtìgbà tí wọ́n ti bí i ló ti yarọ, kò sì rìn rí. 9 Ọkùnrin yìí ń fetí sí Pọ́ọ̀lù bó ṣe ń sọ̀rọ̀. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe tẹjú mọ́ ọn, tó sì rí i pé ó ní ìgbàgbọ́ pé òun lè rí ìwòsàn,+ 10 ó gbóhùn sókè pé: “Dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ.” Ọkùnrin náà fò sókè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn.+
-