11 Gbogbo ohun tí mò ń pa láṣẹ fún yín ni kí ẹ mú wá sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run yín yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà,+ ìyẹn àwọn ẹbọ sísun yín, àwọn ẹbọ yín, àwọn ìdá mẹ́wàá yín,+ ọrẹ látọwọ́ yín àti gbogbo ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà.
12 Ṣé kì í ṣe Hẹsikáyà yìí ló mú àwọn ibi gíga+ Ọlọ́run yín* àti àwọn pẹpẹ Rẹ̀ + kúrò, tó wá sọ fún Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé: “Iwájú pẹpẹ kan ṣoṣo ni kí ẹ ti máa forí balẹ̀, orí rẹ̀ sì ni kí ẹ ti máa mú àwọn ẹbọ yín rú èéfín”?+