-
2 Àwọn Ọba 18:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Ni Élíákímù ọmọ Hilikáyà àti Ṣẹ́bínà+ pẹ̀lú Jóà bá sọ fún Rábúṣákè+ pé: “Jọ̀ọ́, bá àwa ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Árámáíkì*+ torí a gbọ́ èdè náà; má fi èdè àwọn Júù bá wa sọ̀rọ̀ lójú àwọn èèyàn tó wà lórí ògiri.”+ 27 Ṣùgbọ́n Rábúṣákè sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ̀yin àti olúwa yín nìkan ni olúwa mi ní kí n sọ ọ̀rọ̀ yìí fún ni? Ṣé kò tún rán mi sí àwọn ọkùnrin tó ń jókòó lórí ògiri, àwọn tó máa jẹ ìgbẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì máa mu ìtọ̀ ara wọn pẹ̀lú yín?”
-