ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 18:28-35
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 28 Rábúṣákè bá dìde, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì fi èdè àwọn Júù sọ̀rọ̀, ó ní: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Ásíríà.+ 29 Ohun tí ọba sọ nìyí, ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hẹsikáyà tàn yín jẹ, nítorí kò lè gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi.+ 30 Ẹ má sì jẹ́ kí Hẹsikáyà mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, bó ṣe ń sọ pé: “Ó dájú pé Jèhófà máa gbà wá, a ò sì ní fi ìlú yìí lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.”+ 31 Ẹ má fetí sí Hẹsikáyà, torí ohun tí ọba Ásíríà sọ nìyí: “Ẹ bá mi ṣe àdéhùn àlàáfíà, kí ẹ sì túúbá,* kálukú yín á máa jẹ látinú àjàrà rẹ̀ àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, á sì máa mu omi látinú kòtò omi rẹ̀, 32 títí màá fi wá kó yín lọ sí ilẹ̀ tó dà bí ilẹ̀ yín,+ ilẹ̀ ọkà àti ti wáìnì tuntun, ilẹ̀ oúnjẹ àti ti àwọn ọgbà àjàrà, ilẹ̀ àwọn igi ólífì àti ti oyin. Kí ẹ lè máa wà láàyè nìṣó, kí ẹ má sì kú. Ẹ má fetí sí Hẹsikáyà, nítorí ṣe ló ń ṣì yín lọ́nà bó ṣe ń sọ pé, ‘Jèhófà máa gbà wá.’ 33 Ǹjẹ́ ìkankan lára ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè ti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ ọba Ásíríà? 34 Ibo ni àwọn ọlọ́run Hámátì+ àti ti Áápádì wà? Ibo ni àwọn ọlọ́run Séfáfáímù,+ Hénà àti ti Ífà wà? Ǹjẹ́ wọ́n gba Samáríà kúrò lọ́wọ́ mi?+ 35 Èwo nínú gbogbo ọlọ́run àwọn ilẹ̀ náà ló ti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ mi, tí Jèhófà yóò fi gba Jerúsálẹ́mù kúrò lọ́wọ́ mi?”’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́