17 Jèhófà, òótọ́ ni pé àwọn ọba Ásíríà ti pa àwọn orílẹ̀-èdè àti ilẹ̀ wọn run.+18 Wọ́n sì ti ju àwọn ọlọ́run wọn sínú iná, nítorí wọn kì í ṣe ọlọ́run,+ iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn ni wọ́n,+ wọ́n jẹ́ igi àti òkúta. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi lè pa wọ́n run.
15 Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí Hẹsikáyà fi èyí tàn yín jẹ tàbí kó ṣì yín lọ́nà!+ Ẹ má gbà á gbọ́, nítorí kò sí ọlọ́run orílẹ̀-èdè kankan tàbí ìjọba èyíkéyìí tó gba àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ mi àti lọ́wọ́ àwọn baba ńlá mi. Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti Ọlọ́run yín pé á gbà yín lọ́wọ́ mi!’”+