ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 19:1-4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Gbàrà tí Ọba Hẹsikáyà gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó fa ẹ̀wù rẹ̀ ya, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀* bora, ó sì lọ sínú ilé Jèhófà.+ 2 Lẹ́yìn náà, ó rán Élíákímù, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣẹ́bínà akọ̀wé pẹ̀lú àwọn àgbààgbà nínú àwọn àlùfáà, wọ́n fi aṣọ ọ̀fọ̀* bora, ó sì rán wọn sí wòlíì Àìsáyà,+ ọmọ Émọ́ọ̀sì. 3 Wọ́n sọ fún un pé: “Ohun tí Hẹsikáyà sọ nìyí, ‘Ọjọ́ òní jẹ́ ọjọ́ wàhálà àti ti ìbáwí* àti ti ìtìjú; nítorí a dà bí aboyún tó fẹ́ bímọ,* àmọ́ tí kò ní okun láti bí i.+ 4 Bóyá Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ Rábúṣákè tí olúwa rẹ̀ ọba Ásíríà rán láti pẹ̀gàn Ọlọ́run alààyè,+ tí á sì pè é wá jíhìn nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Torí náà, gbàdúrà nítorí àṣẹ́kù+ tó yè bọ́ yìí.’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́