6 Ó sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná+ ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù;+ ó ń pidán,+ ó ń woṣẹ́, ó ń ṣe oṣó, ó sì yan àwọn abẹ́mìílò àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́.+ Ohun búburú tó pọ̀ gan-an ló ṣe lójú Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un bínú.
9 Torí náà, ó sọ fún mi pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì àti Júdà pọ̀ gidigidi.+ Ìtàjẹ̀sílẹ̀ kún ilẹ̀ náà,+ ìwà ìbàjẹ́ sì kún ìlú náà.+ Wọ́n ń sọ pé, ‘Jèhófà ti fi ilẹ̀ wa sílẹ̀, Jèhófà ò sì rí wa.’+