2 Àmọ́ ẹ kórìíra ohun rere,+ ẹ sì fẹ́ràn ohun búburú;+
Ẹ bó àwọn èèyàn mi láwọ, ẹ sì ṣí ẹran kúrò lára egungun wọn.+
3 Ẹ tún jẹ ẹran ara àwọn èèyàn mi,+
Ẹ sì bó wọn láwọ,
Ẹ fọ́ egungun wọn, ẹ sì rún un sí wẹ́wẹ́,+
Bí ohun tí wọ́n sè nínú ìkòkò, bí ẹran nínú ìkòkò oúnjẹ.