-
2 Àwọn Ọba 20:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ní àkókò yẹn, ọba Bábílónì, ìyẹn Berodaki-báládánì ọmọ Báládánì fi àwọn lẹ́tà àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Hẹsikáyà, torí ó gbọ́ pé Hẹsikáyà ṣàìsàn.+ 13 Hẹsikáyà kí wọn káàbọ̀,* ó sì fi gbogbo ohun tó wà nínú ilé ìṣúra+ rẹ̀ hàn wọ́n, ìyẹn fàdákà, wúrà, òróró básámù àti àwọn òróró míì tó ṣeyebíye pẹ̀lú ilé tó ń kó ohun ìjà sí àti gbogbo ohun tó wà nínú àwọn ibi ìṣúra rẹ̀. Kò sí nǹkan tí Hẹsikáyà kò fi hàn wọ́n nínú ilé* rẹ̀ àti nínú gbogbo agbègbè tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀.
-