-
Hósíà 11:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ṣé ó yẹ kí n yọwọ́ lọ́rọ̀ rẹ, ìwọ Éfúrémù?+
Ṣé ó yẹ kí n fà ọ́ lé ọ̀tá lọ́wọ́, ìwọ Ísírẹ́lì?
Ṣé ó yẹ kí n ṣe ọ́ bí Ádímà?
Ṣé ó yẹ kí n ṣe ọ́ bíi Sébóíímù?+
9 Mi ò ní tú ìbínú mi tó ń jó fòfò jáde.
Mi ò ní pa Éfúrémù run mọ́,+
Nítorí Ọlọ́run ni mí, èmi kì í ṣe èèyàn,
Ẹni Mímọ́ tó wà láàárín rẹ;
Mi ò sì ní fi ìbínú wá sọ́dọ̀ rẹ.
-